Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 13:6-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Wọn ni ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí mo fún wọn ní oúnjẹNígbà tí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn tan wọ́n di agbéragaNígbà náà ni wọ́n sì gbàgbé mi.

7. Nítorí náà, Èmi yóò dìde sí wọn bí i kìnnìúnÈmi yóò farapamọ́ dè wọ́n lọ́nà bí i ẹkùn.

8. Béárì igbó tí a já ọmọ rẹ̀ gbàÈmi yóò bá wọn jà bí?Èmi yóò sì fà wọ́n yabí ìgbà tí ẹkùn bá fa ara wọn ya.

9. “A ti pa ọ́ run, ìwọ Ísírẹ́lìnítorí pé ìwọ lòdì sí mi ìwọ lòdì sí olùrànlọ́wọ́ rẹ.

10. Níbo ni ọba rẹ gbé wà nìsisin yìí kí ó bá à le gbà ọ là?Níbo ni àwọn olórí ìlú yín wà,àwọn tí ẹ sọ pé,‘Fún wa ní ọba àti ọmọ aládé’?

11. Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́baNinú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò

12. Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọgbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀

Ka pipe ipin Hósíà 13