Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 13:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Nítorí èyí nínú ìbínú mi ni mo fún un yín lọ́baNinú ìbínú gbígbóná mi, Mo sì mú un kúrò

12. Ẹ̀bi Éfúráímù ni a tí ko jọgbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ wà nínú àkọsílẹ̀

13. Ìrora bí obìnrin tó fẹ́ bímọ ti dé bá aṢùgbọ́n ó jẹ́ ọmọ tí kò lọ́gbọ́nNígbà tí àsìkò tó,ó kọ̀ láti jáde síta láti inú.

14. “Èmi yóò rà wọ́n padà kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú.Èmi yóò rà wọ́n padà lọ́wọ́ ikúIkú, àjàkálẹ̀-àrùn rẹ dà?Isà okú, ìparun rẹ dà?“Èmi kò ní ṣàánú mọ́.

15. Bí ó tilẹ̀ gbilẹ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa yóò wá,Yóò fẹ́ wá láti inú asálẹ̀orísun omi rẹ̀ yóò gbẹkànga rẹ̀ yóò gbẹpẹ̀lú olè yóò fọ́ ilé ẹrùàti gbogbo ilé ìṣúra rẹ̀

16. Ará Sámáríà gbọdọ̀ ru ẹ̀bi wọn,nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run wọn.Wọn ó ti ipa idà ṣubú;a ó fọ́ àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀,A ó sì la àwọn aboyún wọn nínú.”

Ka pipe ipin Hósíà 13