Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 12:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Éfúráímù gbéraga,“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéétàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́”

9. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì;èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì

10. Mo sọ fún àwọn wòlíì,mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́nmo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”

11. Gílíádì ha burú bí?Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì?Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebènínú aporo oko.

12. Jákọ́bù sá lọ si orílẹ̀ èdè Árámù;Ísírẹ́lì sìn kí o tó fẹ ìyàwóó ṣe ìtọjú ẹran láti fi san owó ìyàwó.

13. Olúwa lo wòlíì kan láti mú Ísírẹ́lì jáde wá láti Éjíbítì,nípaṣẹ̀ wòlíì kan ó ṣe ìtọ́jú rẹ̀.

14. Ṣùgbọ́n Éfúráímù ti mú un bínú gidigidi; Olúwa rẹ̀ yóò sì fi ẹ̀bi ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí orí rẹ̀òun yóò sì san án padà fún un nítorí ìwà ẹ̀gàn an rẹ̀.

Ka pipe ipin Hósíà 12