Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 10:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bí igi tó léfòó lórí omi niSamaríà àti àwọn ọba rẹ yóò ṣàn lọ.

8. Àwọn ibi gíga tí ẹ tí ń hùwà buburú ni a o parun—Ẹ̀sẹ̀ Ísírẹ́lì ni.Ẹ̀gún ọ̀gàn àti ẹ̀gún òṣùṣú yóò hù jáde,yóò sì bo àwọn pẹpẹ wọn.Wọn yóò sọ fún àwọn òkè gíga pé, “Bò wá mọ́lẹ̀!”àti fún àwọn òkè kéékèèké pé, “Ṣubú lù wá!”

9. “Láti ìgbà Gíbíà, ni ó ti sẹ̀, ìwọ Ísírẹ́lììwọ sì tún wà níbẹ̀.Njẹ́ ogun kò léẹ̀yin aṣebi ni Gíbíà bá bí?

10. Nígbà tó bá tẹ́ mi lọ́rùn, èmi yóò fi ìyà jẹ wọ́n;Orílẹ̀ èdè yóò kó ra wọn jọ wọ́n ó sì dojú kọ wọnLáti fi wọn sínú ìdè nítorí ìlọ́po ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

11. Éfúráímù jẹ́ ọmọ màlúù tí atí kọ́, to si fẹ́ràn láti máa pa ọkàlórí ọrun rẹ̀ tó lẹ́wà nièmi ó dí ẹru wúwo léÈmi yóò mú kí a gun Éfúráímù bí ẹṣinJúdà yóò tú ilẹ̀,Jákọ́bù yóò sì fọ́ ogúlùtu rẹ̀

12. Ẹ gbin òdòdó fún ara yínkí ẹ sì ká èso ìfẹ́ àìlópin,Ẹ tu ilẹ̀ yín tí a kòronítorí pé ó ti tó àsìkò láti wá Olúwa,títí tí yóò fi dé,tí yóò sì rọ òjò òdodo lé yín lórí.

13. Ṣùgbọ́n ẹ tí gbìn buburú ẹ si ka ibi,Ẹ ti jẹ èso èkénítorí ẹ tí gbẹ́kẹ̀ lé agbára yínàti àwọn ọ̀pọ̀ jagun jagun yín

Ka pipe ipin Hósíà 10