Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hágáì 1:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọdún kejì ọba Dáríúsì ní ọjọ́ kìn-ín ní okìn-ín-ní oṣù kẹfà, ọ̀rọ̀ Olúwa wá nípasẹ̀ wòlíì Hágáì sí Serubábéli ọmọ Séítélì, Baálẹ̀ Júdà, àti Sọ́dọ̀ Jósúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà.

2. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Àwọn ènìyàn wọ̀nyí wí pé, ‘Kò ti to àkókò láti kọ́ ilé Olúwa.’ ”

3. Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hágáì wí pé:

4. “Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fún ra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀sọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?”

5. Ní sinsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsí ọ̀nà yín.

6. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; Ẹ̀yin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”

7. Báyìí ni Olúwa alágbára wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

Ka pipe ipin Hágáì 1