Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 4:8-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ó sì tún fún un ní ọ̀kan lára ìwé tí ó gbé jáde fún ìparun àwọn, èyí tí a tẹ̀ jáde ní Ṣúṣà, láti fi han Ésítà kí ó sì ṣe àlàyé e rẹ̀ fún-un, ó sì sọ fún-un pé kí ó bẹ̀ ẹ́ kí ó lọ ṣíwájú ọba láti bẹ̀bẹ̀ fún àánú, kí ó bẹ̀bẹ̀ nítorí àwọn ènìyàn an rẹ̀.

9. Hátakì padà ó sì lọ ṣàlàyé fún Ẹ́sítà ohun tí Módékáì sọ.

10. Nígbà náà ni Ésítà pàṣẹ fún un pé kí ó sọ fún Módékáì,

11. “Gbogbo àwọn ìjòyè ọba àti àwọn ènìyàn agbègbè ìjọba rẹ̀ mọ̀ wí pé: fún ẹnikẹ́ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tàbí tí ó bá bá ọba sọ̀rọ̀ láì jẹ́ pé a ránsẹ́ pèé (ọba ti gbé òfin kan kalẹ̀ pé) kíkú ni yóò kú. Ohun kan tí ó le yẹ èyí ni pé, kí ọba na ọ̀pá a góòlùu rẹ̀ síi kí ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí. Ṣùgbọ́n, ọgbọ̀n ọjọ́ ti kọjá tí a ti pè mí láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba.”

12. Nígbà tí a sọ ọ̀rọ̀ Ẹ́sítà fún Módékáì,

13. Ó sì rán ìdáhùn yí sí i pé; “Má ṣe rò pé nítorí pé ìwọ wà nílé ọba ìwọ nìkan lè yọ láàrin gbogbo àwọn Júù.

14. Nítorí bí ìwọ bá dákẹ́ ní àkókò yìí, ìrànlọ́wọ́ àti ìtúsílẹ̀ fún àwọn Júù yóò dìde láti ibòmíràn, Ṣùgbọ́n ìwọ àti àwọn ìdílée bàbá à rẹ yóò ṣègbé. Taa ni ó mọ̀ wí pé nítorí irú àkókò yìí ni o ṣe wà ní ipò ayaba?”

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 4