Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 8:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni àwọ̀n olórí ìdílé àti àwọn tí ó fi orúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn tì wọn gòkè pẹ̀lú mi làti Bábílónì ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba:

2. Nínú àwọn ọmọ Fínéhásì, Gásómù;nínú àwọn ọmọ Ítamárì, Dáníẹ́lì;nínú àwọn ọmọ Dáfídì, Hátúsì,

3. nínú àwọn ọmọ Ṣekaníáyà;nínú àwọn ọmọ Párósì, Ṣekaríáyà, àti pé àádọ́jọ (150) ọkùnrin fi orùkọ sílẹ̀ pẹ̀lú rẹ;

4. nínú àwọn ọmọ Pahati-Móábù, Elehóénáyì ọmọ Seraíyà àti àwọn igba (200) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

5. nínú àwọn ọmọ Ṣátù, Ṣekaníáyà ọmọ Jahasíélì àti àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

6. nínú àwọn ọmọ Ádínì, Ébédì ọmọ Jónátanì, àti àádọ́ta (50) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

7. nínú àwọn ọmọ Élámù, Jésáíyà ọmọ Ataláyà àwọn àádọ́rin (70) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

8. nínú àwọn ọmọ Ṣéfátayà, Ṣébádáyà ọmọ Míkẹ́lì, àti ọgọ́rin (80) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

9. nínú àwọn ọmọ Jóábù, Ọbádáyà ọmọ Jéhíélì àti ogun-ó-lugba-ó-din méjì (218) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

10. nínú àwọn ọmọ Bánì, Ṣélómútì ọmọ Jósífáyà àti ọgọ́jọ 160 ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

11. nínú àwọn ọmọ Bébáì, Sakaráyà ọmọ Bébáì àti ọkúnrin 45 méjìdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú rẹ̀;

12. nínú àwọn ọmọ Ásígádì, Johánánì ọmọ Hákátanì, àti àádọ́fà (110) ọkùnrin pẹ̀lú rẹ̀;

13. nínú àwọn ọmọ Ádóníkámù, àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orùkọ wọn ń jẹ̀ Élífélétì, Jéúélì àti Ṣémáyà, àti ọgọ́ta (60) ọkúnrin pẹ̀lú wọn;

14. Nínú àwọn ọmọ Bígífáyì, Hútayì àti Ṣákúrì, àti àádọ́rin 70 ọkúnrin pẹ̀lú wọn.

15. Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 8