Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 2:65-70 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

65. Yàtọ̀ sí ẹgbẹ̀ríndínlẹ́gbàárin-ó-dín mẹ́talélọ́gọ́ta (7,337) ìránṣẹ́ ọkùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin; wọ́n ní igba (200) akọrin ọkùnrin àti obìnrin.

66. Wọ́n ní ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin-ó-dín mẹ́rin ẹṣin (736); ìbaka òjìlélúgba-ó-lé-márùn-ún (245)

67. Ràkúnmí jẹ́ irinwó-ó-lé-márùndínlógójì; (435) àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹgbẹ̀rínlélọ́gbọ̀n-ó-dín-ọgọ́rin (6,720).

68. Ní ìgbà tí wọ́n dé ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, díẹ̀ nínú àwọn olórí àwọn ìdílé fi ọrẹ àtinúwá silẹ̀ fún ṣíṣe àtúnkọ́ ilé Ọlọ́run ní ààyè rẹ̀.

69. Gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, wọ́n fún ilé ìṣúra fún iṣẹ́ yìí ní ọ̀kẹ́ mẹ́ta (61,000) ìwọ̀n dírámà wúrà, ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n fàdákà (5,000) àti ọgọ́rùn-ún (100) ẹ̀wù àlùfáà.

70. Àwọn àlùfáà, àwọn ará Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́bodè àti àwọn ìránṣẹ́ ilé Olúwa ṣe àtìpó sínú àwọn ìlú wọn, pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn, àti ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àtìpó sínú ìlú u wọn.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 2