Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 10:15-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Jónátanì ọmọ Ásáhélì àti Jáhéséáyà ọmọ Jíkífà nìkan pẹ̀lú àtìlẹyìn Mésísúlámù àti Ṣíábétaì ará Léfì, ni wọ́n tako àbá yìí.

16. Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n se fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Ẹ́sírà yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jòkóó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà,

17. Ní ọjọ́ kìn-ní-ní oṣù kìn-ní-ní ni wọn parí pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì.

18. Lára ìran àwọn àlùfáà àwọn wọ̀nyí fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì:Nínú ìran Jésíúà ọmọ Jósádákì, àti àwọn arákùnrin rẹ: Mááséáyà, Élíásérì, Járíbù àti Gédáláyà.

19. Gbogbo wọn ni wọ́n Ṣe ìpinnu láti lé àwọn ìyàwó wọn lọ, wọ́n sì fi àgbò kan láàrin agbo ẹran lé lẹ̀ fún ẹ̀bi wọn gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀

20. Nínú ìran Ímérì:Hánánì àti Ṣébádáyà.

21. Nínú ìran Hárímù:Mááséáyà, Élíjà, Ṣíhémáyà, Jébíélì àti Úsáyà.

22. Nínú ìran Pásíhúrì:Élíónáì, Mááséáyà, Ísímáílì, Nétaníẹ́lì, Jósábádì àti Élásáì.

23. Lára àwọn ọmọ Léfì:Jósábádì, Ṣíhíméì, Kéláéáyà (èyí tí í se Kélítà), Pétíáíyà, Júdà àti Élíásérì.

24. Nínú àwọn akọrin:Élíásíbù.Nínú àwọn asọ́nà:Sálúmù, Télémù àti Úrì.

25. Àti lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tókù:Nínú ìran Párósì:Rámíáyà, Ísíáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Éléásánì, Málíkíjà àti Bénáíyà.

26. Nínú ìran Élámù:Mátaníáyà, Ṣékáríáyà, Jéhíélì, Ábídì, Jérémótì àti Élíjà.

27. Nínú àwọn ìran Ṣátítù:Élíóénáì, Élísíbù, Mátaníáyà, Jérémótì, Ṣábádì àti Ásísà.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 10