Ní ọdún kìn-ní-ní Ṣáírúsì, ọba Páṣíà, kí a lè mú ọ̀rọ̀ Olúwa tí Jeremáyà sọ ṣẹ, Olúwa ru ọkàn Ṣáírúsì ọba Páṣíà sókè láti ṣe ìkéde jákèjádò gbogbo agbégbé ìjọba rẹ̀, kí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: