Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 5:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Àwa ti di aláìní òbí àti aláìní baba,àwọn ìyá wa ti di opó.

4. A gbọdọ̀ ra omi tí à ń mu;igi wa di títà fún wa.

5. Àwọn tí ó ń lé wa sún mọ́ wa;àárẹ̀ mú wa àwa kò sì rí ìsinmi.

6. Àwa jọ̀wọ́ ara wa fún Éjíbítì àti Ásíríàláti rí oúnjẹ tótó jẹ.

7. Àwọn baba wa ti ṣẹ̀, wọn kò sì sí mọ́,àwa sì ń ru ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

8. Àwọn ẹrú ń jọba lórí wa,kò sì sí ẹni tí yóò gbà wá lọ́wọ́ wọn.

9. Àwa ń rí oúnjẹ wa nínú ewu ẹ̀mí wanítorí idà tí ó wà ní ihà.

10. Ẹran ara wa gbóná bí ààrò,ebi sì yó wa bí àárẹ̀.

11. Wọ́n ti fipá bá àwọn obìnrin wa lò pọ̀ ní Síónì,àti àwọn wúndíá wa ní ìlú Júdà.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 5