Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 5:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àwọn ọmọ ọbakùnrin ti di ṣíṣo sókè ní ọwọ́ wọn;kò sí ìbọ̀wọ̀ fágbà mọ́.

13. Àwọn ọdọ́mọkùnrin wa ru òkúta;àwọn ọmọkùnrin sì ńṣsàárẹ̀ lábẹ́ ẹrù igi.

14. Àwọn àgbààgbà ti lọ kúrò ní ẹnu bodè ìlú;àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì dákẹ́ orin wọn

15. Ayọ̀ ti ṣáko ní ọkàn wa;ọ̀fọ̀ sì ti dúró bí ijó fún wa.

16. Adé ti sí kúrò ní orí waÈgbé ni fún wa, nítorí a ti ṣẹ̀.

17. Nítorí èyí, àárẹ̀ mú ọkàn wa,nítorí èyí, ojú wa sì ṣú.

18. Fún òkè Síónì tí ó ti di ahorolórí rẹ̀ àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ sì ń rìn kiri.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 5