Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 6:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. “Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”

12. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”

13. Olúwa bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

Ka pipe ipin Ékísódù 6