Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 37:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Bésálélì se àpótí igi kasíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀.

2. Ó fi kìkì wúrà bò ó nínú àti lóde, ó sì fi wúrà gbà á léti yíká.

3. Ó sì dá òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ìhà kìn-ín-ní àti òrùka méjì ni ìhà kejì.

4. Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.

5. Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.

6. Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 37