Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 35:2-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.

3. Ẹ má se dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

4. Mósè sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pa láṣẹ:

5. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;

6. aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;

7. awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kaṣíá;

8. òróró ólífì fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

9. Òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù èfòdì àti igbáàyà.

10. “Gbogbo ẹni tí ó ní ọgbọ́n láàrin yín, kí ó wa, kí ó sì wá se gbogbo ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ:

11. Àgọ́ náà pẹ̀lú àgọ́ rẹ àti ìbòrí rẹ̀, kọ́kọ́rọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ọ̀wọ́n rẹ̀ àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

12. Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó;

13. Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;

14. Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;

15. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà;

16. Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú àrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

17. aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà;

18. Èèkàn àgọ́ náà fún Àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;

19. aṣọ híhun láti sisẹ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”

Ka pipe ipin Ékísódù 35