Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 35:12-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Àpótí náà pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀, ibò àánú àti aṣọ títa náà tí ó síji bòó;

13. Tábìlì náà pẹ̀lú òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn náà;

14. Ọ̀pá fìtílà tí ó wà fún títanná pẹ̀lú ohun èlò rẹ̀, fìtílà àti òróró fún títanná;

15. Pẹpẹ tùràrí náà pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀, òróró ìtasórí àti tùràrí dídùn; aṣọ títa fún ọ̀nà ìlẹ̀kùn ní ẹnu ọ̀nà sí Àgọ́ náà;

16. Pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú ojú àrò idẹ rẹ̀, òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀; agbada idẹ pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

17. aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú, ọ̀wọ́n àti ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ àti aṣọ títa fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà;

18. Èèkàn àgọ́ náà fún Àgọ́ náà àti fún àgbàlá àti okùn wọn;

19. aṣọ híhun láti sisẹ ní ibi mímọ́ aṣọ mímọ́ fún Árónì àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n sìn bí àlùfáà.”

20. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì kúrò níwájú Mósè,

21. Olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ àti ẹni tí ọkàn rẹ̀ gbé sókè wá, wọ́n sì mú ọrẹ fún Olúwa, fún isẹ́ Àgọ́ àjọ, fún gbogbo ìsìn rẹ̀ àti fún asọ mímọ́ náà.

22. Gbogbo àwọn tí ó fẹ́, ọkùnrin àti obìnrin, wọ́n wá wọ́n sì mú onírúurú ìlẹ̀kẹ wúrà: òrùka etí, òrùka àti ọ̀sọ́. Gbogbo wọn mú wúrà gẹ́gẹ́ bí ọrẹ wá fún Olúwa.

23. Olúkúlùkù ẹni tí ó ni aṣọ aláró elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára, tàbí irun ewúrẹ́, awọ àgbò tí a rì ní pupa tàbí awọ màlúù odò, kí ó mú wọn wá.

24. Àwọn tí ó mú ọrẹ fàdákà tàbí idẹ wá, mú ọrẹ wá fún Olúwa, àti olúkúlùkù ẹni tí ó ní igi kasíà fún ipa kankan nínú iṣẹ mú un wá.

25. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó ní ọgbọ́n ríran owú pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀, kí ó mú èyí ti ó ti ran wá ti aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó tàbí ti ọ̀gbọ̀ dáradára.

26. Gbogbo àwọn obìnrin tí ó fẹ́, tí ó sì ní ọgbọ́n ń ran òwú irun ewúrẹ́

27. Àwọn olórí mú òkúta óníkísì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù éfódì àti igbáàyà.

28. Wọ́n sì tún mú olóòrùn àti òróró ólífì wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.

29. Gbogbo àwọn ènìyàn Isirẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún wọn láti se nípaṣẹ̀ Mósè.

30. Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà,

31. Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un, pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú isẹ́ ọnà

32. Láti má a se aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ,

Ka pipe ipin Ékísódù 35