Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 35:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mósè pe gbogbo ìjọ Ísírẹ́lì ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti Olúwa ti pa láṣẹ fún-un yín láti ṣe:

2. Fún ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje yóò jẹ́ ọjọ́ mímọ́ fún yín, ọjọ́ ìsinmi ni sí Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ni ọjọ́ náà ní a ó pa.

3. Ẹ má se dáná kankan ní ibùgbé yín ní ọjọ́ ìsinmi.”

4. Mósè sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pa láṣẹ:

5. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;

6. aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;

7. awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kaṣíá;

Ka pipe ipin Ékísódù 35