Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 34:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé, “E gé òkúta wàláà méjì jáde bí i ti àkọ́kọ́, èmi yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìwé tó wà lára tí àkọ́kọ́ tí ìwọ ti fọ́ sára wọn.

2. Múra ní òwúrọ̀, kí o sì wá sórí òkè Ṣínáì. Kí o fi ara rẹ hàn mí lórí òkè náà.

3. Ẹnìkẹ́ni kò gbọdọ̀ wá pẹ̀lú rẹ tàbí kí a rí wọn lórí òkè náà; bẹ́ẹ̀ ni agbo àgùntàn tàbí ọwọ́ ẹran kó má ṣe jẹ níwájú òkè náà.”

4. Bẹ́ẹ̀ Mósè sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sínáì lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún-un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀.

5. Nígbà náà ni Olúwa sọ̀kalẹ̀ nínú àwọ̀ọ̀sánmọ̀, ó sì dúró níbẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pòkìkí orúkọ Olúwa.

6. Ó sì kọjá níwájú Mósè, ó sì ń ké pé, “Olúwa, Olúwa, Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú, tí ó pọ̀ ní ìfẹ́ àti olóòtítọ́,

7. Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1000), ó sì ń dárí jin àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń sọ̀tẹ̀ àti elẹ́sẹ̀. Ṣíbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ìkẹrin.”

Ka pipe ipin Ékísódù 34