Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 33:9-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Bí Mósè ṣe wọ inú àgọ́ náà, ọ̀wọ̀n àwọ̀ọsánmọ̀ yóò sọ̀kalẹ̀, yóò sì dúró sí ẹnu ọnà, nígbà tí Olúwa ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Mósè.

10. Nígbàkígbà tí àwọn ènìyàn bá rí i ti ọ̀wọ́n àwọ̀ọsánmọ̀ bá dúró ní ẹnu ọ̀nà àgọ́, gbogbo wọn yóò dìde wọn yóò sì sìn, olúkúlùkù ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀.

11. Olúwa máa ń bá Mósè sọ̀rọ̀ lójúkorojú, gẹ́gẹ́ bí i pé ènìyàn ń bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀. Nígbà náà ni Mósè yóò tún padà lọ sí ibùdó, ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin Jósúà ìránṣẹ́ rẹ̀ ọmọ Núnì kò fi àgọ́ sílẹ̀.

12. Mósè sọ fún Olúwa pé, “Ìwọ ti ń sọ fún mi, ‘Darí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,’ ṣùgbọ́n ìwọ kò jẹ́ kí ń mọ ẹni tí ìwọ yóò rán pẹ̀lú mi. Ìwọ ti wí pé, ‘Èmi mọ̀ ọ́ nípa orúkọ, ìwọ sì ti rí ojú rere mi pẹ̀lú.’

13. Bí ìwọ bá ní inú dídùn pẹ̀lú mi, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ, kí èmi kí ó lè mọ̀ ọ́, kí n sì le máa wá ojú rere rẹ pẹ̀lú. Rántí wí pé orílẹ̀ èdè yìí ènìyàn rẹ ni.”

14. Olúwa dáhùn wí pé, “Ojú mi yóò máa bá ọ lọ, èmi yóò sì fún ọ ní ìsinmi.”

15. Nígbà náà ni, Mósè wí fún-un pé, “Bí ojú rẹ kò bá bá wa lọ, má se rán wa gòkè láti ìhín lọ.

16. Báwo ni ẹnìkẹ́ni yóò se mọ̀ pé inú rẹ dùn pẹ̀lú mi àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ àyàfi ti o bá bá wa lọ? Kí ni yóò lè yà mí àti àwọn ènìyàn rẹ kúrò lára gbogbo ènìyàn tí ó wà ní ayé?”

Ka pipe ipin Ékísódù 33