Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 30:25-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ṣe ìwọ̀nyí ní òróró mímọ́ ìkunra, tí a pò pọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣe-òórùn dídùn tì í ṣe, Yóò jẹ òróró mímọ́ ìtasórí.

26. Ìwọ yóò sì lò ó láti ya àgọ́ sí mímọ́ àti àpótí ẹ̀rí náà,

27. tábìlì àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ọ̀pá fìtílà àti ohun èlò rẹ̀, àti pẹpẹ tùràrí,

28. pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti agbada pẹ̀lú ẹṣẹ̀ rẹ̀.

29. Ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fí ọwọ́ kàn wọn yóò di mímọ́.

30. “Ìwọ yóò sì ta òróró sí orí Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ìwọ yóò sì sọ wọ́n di mímọ́, nítorí kí wọn lè sìn mí bí àlùfáà.

31. Ìwọ yóò sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Èyí ni yóò ṣe òróró mímọ́ ìtasórí mi fún ìrandíran tó ń bọ̀.

32. Má se dà á sí ara ènìyàn kí o má sì ṣe ṣe òróró kankan ni irú rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ̀yín sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

33. Ẹnikẹ́ni tí ó bá po irú rẹ̀, tàbí ẹnikẹ́ni tí ó bá fi sára ẹnìkankan yàtọ̀ sí àlùfáà, a ó gé e kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.’ ”

34. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Mú tùràrí olóòórùn dídùn sọ́dọ̀ rẹ, óníkà, àti gálíbánúmù àti kìkì tùràrí dáradára, iye kan ni gbogbo rẹ,

35. ṣe tùràrí olóòórùn dídùn tí a pò, iṣẹ́ àwọn olóòórùn, tí ó ní iyọ̀, ó dára, ó sì jẹ́ mímọ́.

36. Ìwọ yóò sì lọ díẹ̀ nínú rẹ̀ kúnná, ìwọ yóò sì gbé e ṣíwájú ẹ̀rí ní àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti pàdé yín. Yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ fún yín.

37. Ẹ má ṣe se tùràrí kankan ní irú èyí fún'ra yín; ẹ kà á ní mímọ́ sí Olúwa.

38. Ẹnikẹ́ni tí ó bá se irú rẹ̀ láti máa gbádùn òórùn rẹ̀, òun ni a ó gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.”

Ka pipe ipin Ékísódù 30