Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 28:27-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Ìwọ yóò sì se orùkọ wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù ẹ́fó dì méjèèjì ní ìṣẹ̀lẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó kọ́jú sí ìṣẹ̀lú rẹ̀, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù éfódì náà.

28. Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù èfòdì pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà.

29. “Nígbà kúgbà tí Árónì bá wọ ibi mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Ẹ̀yà méjìlá) ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.

30. Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa.

31. “Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró,

32. pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrin rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìsẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.

33. Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 28