Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 28:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Òkúta méjìlá (12) yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.

22. “Fún ìgbàyà náà, ìwọ yóò se okùn ẹ̀wọ̀n ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè.

23. Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì fún un, kí o sì so wọ́n mọ́ igun igbá àyà méjèèjì.

24. Ìwọ yóò so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì mọ́ òrùka ní igun ìgbàyà náà,

25. àti eti ẹ̀wọ̀n méje ni kí o so mọ́ ojú ìdè méjèèjì, kí o sì fi sí èjìká ẹ̀wù éfódì náà níwájú.

26. Ìwọ yóò ṣe òrùka wúrà méjì, ìwọ yóò sì so wọ́n mọ́ igun méjì igbáàyà kejì ní ìhà inú tí ó ti ẹ̀wù éfódì náà.

27. Ìwọ yóò sì se orùkọ wúrà méjì, ìwọ yóò sì fi wọ́n sí èjìká ẹ̀wù ẹ́fó dì méjèèjì ní ìṣẹ̀lẹ̀, sí ìhà iwájú rẹ̀, tí ó kọ́jú sí ìṣẹ̀lú rẹ̀, lókè onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù éfódì náà.

28. Wọn yóò sì so òrùka ìgbàyà mọ́ òrùka ẹ̀wù èfòdì pẹ̀lú ọ̀já aláró, pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, kí a má ba à tú ìgbàyà náà kúrò lára ẹ̀wù èfòdì náà.

29. “Nígbà kúgbà tí Árónì bá wọ ibi mímọ́, òun yóò ru orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (Ẹ̀yà méjìlá) ní gbogbo ọ̀kan rẹ̀ ni ìgbàyà ìpinu bí ìrántí nígbà gbogbo níwájú Olúwa.

30. Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa.

31. “Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró,

Ka pipe ipin Ékísódù 28