Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 28:2-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Árónì arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

3. Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Árónì, fún ìyà-sí-mímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

4. Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

5. Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.

6. “Wọn yóò sì dá ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, tí aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókún wíwẹ́ iṣẹ́ ọlọ́nà.

7. Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.

8. Àti onírúurú ọnà ọ̀já rẹ̀, tí ó wà ni orí rẹ̀, yóò rí bákan náà, gẹ́gẹ́ bi iṣẹ́ rẹ̀, tí wúrà, ti aṣọ aláró, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́.

9. “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkísì méjì, ìwọ yóò sì fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sára wọn.

10. Ní ti ìbí wọn, orúkọ àwọn mẹ́fà sára òkúta kan àti orúkọ àwọn mẹ́fà tókù sára òkúta kejì.

11. Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.

12. Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká èfòdì náà ní òkúta ìràntí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Árónì yóò sì máa ní orúkọ wọn ní wájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.

13. Ìwọ yóò sì ṣe ojú ìdè wúrà

14. Àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.

15. “Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára.

Ka pipe ipin Ékísódù 28