Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 28:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ìwọ sì mú Árónì arákùnrin rẹ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, mú un kúrò ni àárin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ Nádáhù, Ábíhù, Élíásárì, àti Ítamárì, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

2. Ìwọ yóò sì dá aṣọ mímọ́ fún Árónì arákùnrin rẹ, láti fún un ni ọ̀ṣọ́ àti ọlá.

3. Ìwọ yóò sì sọ fún gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, àwọn ẹni tí mo fún ní ọgbọ́n, kí wọn kí ó lè dá aṣọ fún Árónì, fún ìyà-sí-mímọ́ rẹ̀, kí ó lè ba à sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

4. Wọ̀nyí ni àwọn aṣọ tí wọn yóò dá: ìgbàyà kan, ẹ̀wù èfòdì, ọ̀já àmùrè kan, ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ ọlọ́nà, fìlà àti aṣọ ìgúnwà. Kí wọn kí ó dá àwọn aṣọ mímọ́ yìí fún Árónì arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọn kí ó lè sìn mí gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

5. Wọn yóò sì lo wúrà, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ dáradára.

6. “Wọn yóò sì dá ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, tí aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókún wíwẹ́ iṣẹ́ ọlọ́nà.

7. Kí ó ni aṣọ èjìká méjì tí a so mọ́ igun rẹ̀ méjèèjì, kí a lè so ó pọ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 28