Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 25:2-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn mú ọrẹ wá fún mi ìwọ yóò gba ọrẹ náà fún mi ni ọwọ́ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan ti ọkàn rẹ bá fẹ́ láti fi fún mi.

3. Wọ̀nyí ni ọrẹ ti ìwọ yóò gbà ni ọwọ́ ọ wọn: wúrà, fàdákà, idẹ,

4. aṣọ aláwọ̀ aró, aṣọ aláwọ̀ aró-fẹ́ẹ́rẹ́, aṣọ aláwọ̀ òdòdó, aṣọ funfun-láú, ìrun ewúrẹ́.

5. Awọ àgbò tí a rẹ ní pupa àti awọ ewúrẹ́-dò; igi kásíà;

6. Òróró olífì fún iná títàn, òróró olóórùn dídùn fún ìtasórí àti fún tùràrí olóórùn dídùn,

7. àti òkúta oníkì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù éfódi àti ẹ̀wù ìgbàyà.

8. “Nígbà náà ni ìwọ yóò jẹ́ kí wọn kọ́ ibi mímọ́ fún mi. Èmi yóò sì máa gbé ní àárin wọn.

9. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fi hàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.

10. “Kí wọn kí ó fi igi kasíà ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.

11. Bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó wúrà, bò ó ni inú àti ìta kí o sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.

Ka pipe ipin Ékísódù 25