Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 25:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Fi igi kaṣíà ṣe òpó mẹ́rin, kí o sì fi wúrà bò ó.

14. Fi òpó náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí náà láti fi gbé e.

15. Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a ko ní yọ wọ́n kúrò.

16. Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà.

17. “Ojúlówó wúrà ni kí o fi se ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀.

18. Fi wúrà tí a lù se kérúbù méjì sí igun ìtẹ́-àánú.

Ka pipe ipin Ékísódù 25