Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 24:13-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà ni Mósè jáde lọ pẹ̀lú Jọsúà arákùnrin rẹ̀. Mósè lọ sí orí òkè Ọlọ́run.

14. Ó sì wí fún àwọn àgbààgbà pé, Ẹ dúró dè wá níhìn-ín yìí, títí àwa yóò fi tún padà tọ̀ yín wá, sì kíyèsìí, Árónì àti Húrì ń bẹ pẹ̀lú yín, bí ẹnikan bá ni ọ̀ràn kan, kí ó tọ̀ wọ́n lọ.

15. Nígbà tí Mósè gun orí òkè lọ, ìkúúkùù bo orí òkè náà.

16. Ògo Olúwa sì wà ní orí òkè Ṣí náì. Ìkùùkuu bo orí òkè náà fún ọjọ́ mẹ́fà, ni ọjọ́ keje ni Olúwa kọ sí Mósè láti inú ìkùùkuu náà wá.

17. Ni ojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ògo Olúwa náà dà bí iná ajónirun ni orí òkè.

18. Nígbà náà ni Mósè wọ inú ìkùùkuu náà bí ó ti ń lọ ní orí òkè. Ó sì wà ni orí òkè náà ni ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

Ka pipe ipin Ékísódù 24