Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 23:2-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. “Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ̀pọ̀ ènìyàn láti se aburú. Nígbà tí ìwọ bá jẹ́rìí sí ẹjọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po nípa gbígbé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ènìyàn.

3. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúṣáájú sí talákà nínú ẹjọ́ rẹ̀.

4. “Bí ìwọ bá se alábàápàdé akọ màlúù tàbí akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ọ̀ta rẹ tí ó sinà lọ, rí i dájú pé o mú un padà wá fún un.

5. Bí ìwọ bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ẹnìkan tí ó koríra rẹ tí ẹrù subú lé lórí, má ṣe fi í sílẹ̀ bẹ́ẹ̀; rí i dájú pé o ran án lọ́wọ́ nípa rẹ.

6. “Ìwọ kò gbọdọ̀ du aláìní ní ìdájọ́ òdodo.

7. Má ṣe lọ́wọ́ nínú ẹ̀sùn èké, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ pa aláìṣẹ̀ tàbi olódodo ènìyàn, nítorí èmi kò ní dá ẹlẹ́bí láre.

8. “Ìwọ kò gbọdọ̀ gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ máa ń fọ àwọn tó ríran lójú, a sì yí ọ̀rọ̀ olódodo po.

9. “Ìwọ kò gbọdọ pọ́n àlejò kan lójú sa ti mọ inú àlejò, nítorí ẹ̀yin náà ti jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

10. “Ní ọdún mẹ́fà ni ìwọ yóò gbin oko rẹ, ìwọ yóò sì kóre èso rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, jẹ́ kí ilẹ̀ náà wà ní àìkọ àti ní àìlò, jẹ́ kí ilẹ̀ náà kí ó sinmi. Nígbà náà ni talákà láàrin yín yóò rí oúnjẹ láti ibẹ̀. Ẹranko igbó yóò sì jẹ èyí tí wọ́n fi sílẹ̀. Ìwọ ṣe bákan náà pẹ̀lú ọgbà-àjàrà rẹ àti ọgbà Olífì rẹ.

12. “Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò ṣe iṣẹ́ rẹ, ìwọ yóò sì sinmi ní ọjọ́ keje, kí akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ bá à lè ní ìsinmi, kí a sì tú ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ àti àlejò ti ń gbé ni ilé rẹ lára.

13. “Ẹ máa sọ́ra, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí mo wí fún un yín. Ẹ má se pe orúkọ òrìṣà, kí a má se gbọ́ orúkọ wọn ní ẹnu yín.

Ka pipe ipin Ékísódù 23