Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 21:32-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Bí akọ màlúù bá kan ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin pa, olówó rẹ̀ yóò san ọgbọ̀n sékélì fàdákà fún ẹni tó ni ẹrú, a ó sì sọ akọ màlúù náà ni okúta pa.

33. “Bí ọkùnrin kan bá sí kòtò sílẹ̀ láìbò tàbí kí ó gbẹ́ kòtò sílẹ̀ láìbò, tí màlúù tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá se bẹ́ẹ̀ bọ́ sínú kòtò náà.

34. Ẹni tí ó ni kòtò yóò san owó àdánù yìí fún ẹni tí ó ni ẹran. Òkú ẹran náà yóò sì di tirẹ̀.

35. “Bí akọ màlúù ọkùnrin kan bá pa akọ màlúù ẹlòmíràn lára tí ó sì kú, wọn yóò ta akọ màlúù tó wà láàyè, wọn yóò sì pín owo èyí ti wọn tà àti ẹran èyí tí ó kú dọ́gbadọ́gba.

36. Ṣùgbọ́n tí ó bá ti di ìgbà gbogbo tí akọ màlúù náà máa ń kan òmíràn, tí olówó rẹ̀ kò sì mú un so, olówó rẹ̀ yóò san ẹran dípò ẹran. Ẹran tí ó kú yóò sì jẹ́ tirẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 21