Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 18:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gésómù (àjòjì); nítorí Mósè wí pé, “Èmi ń se àlejò ni ilẹ̀ àjòjì.”

4. Èkejì ń jẹ́ Élíásérì (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Fáráò.”

5. Jẹ́tírò, àna Mósè, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mósè tọ̀ ọ́ wá nínú ihà tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run.

6. Jẹ́tírò sì ti ránṣẹ́ sí Mósè pé, “Èmi Jẹ́tírò, àna rẹ, ni mo ń bọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, èmi àti aya àti àwọn ọmọkùnrin rẹ méjèèjì.”

7. Mósè sì jáde lọ pàdé rẹ̀, ó tẹríba fún un, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu. Wọ́n kí ara wọn, wọ́n yọ̀ mọ́ ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ.

8. Mósè sọ fún àna rẹ̀ nípa ohun gbogbo ti Olúwa tí se sí Fáráò àti àwọn ará Éjíbítì nítorí Ísírẹ́lì. Ó sọ nípa gbogbo ìṣòro tí wọn bá pàdé ní ọ̀nà wọn àti bí Olúwa ti gbà wọ́n là.

9. Inú Jẹ́tírò dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

10. Jẹ́tírò sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì gbà àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì.

11. Mo mọ nísinsìnyìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Éjíbítì.”

Ka pipe ipin Ékísódù 18