Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 18:23-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni ìtẹ́lọ́rùn.”

24. Mósè fetísílẹ̀ sí àna rẹ̀, ó sì ṣe ohun gbogbo tí ó wí fún un.

25. Mósè sì yan àwọn ènìyàn tí wọ́n kun ojú òsùwọ̀n nínú gbogbo Ísírẹ́lì; ó sì fi wọ́n ṣe olórí àwọn ènìyàn, olórí ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rùn, ọgọ́rùn ún ọgọ́rùn ún, àádọ́ta-àádọ́ta, àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.

26. Wọ́n sì ń ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ní ìgbà gbogbo. Wọ́n sì ń mú ẹjọ́ tó le tọ Mósè wá; ṣùgbọ́n wọ́n ń dá ẹjọ́ tí kò le fún rawọn

27. Mósè sì jẹ́ kí àna rẹ̀ lọ ní ọ̀nà rẹ̀, Jẹ́tírò sì padà sí ilẹ̀ ẹ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 18