Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 18:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Jẹ́tírò, àlùfáà Mídíánì, àna Mósè, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún Mósè àti fún Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn rẹ̀, àti bí Olúwa ti mú àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti Éjíbítì wá.

2. Nígbà náà ni Jẹ́tírò mu aya Mósè tí í se Ṣípórà padà lọ sọ́dọ̀ rẹ (Nítorí ó ti dá a padà sí ọ̀dọ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀).

3. Òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì. Orúkọ Àkọ́bí ń jẹ́ Gésómù (àjòjì); nítorí Mósè wí pé, “Èmi ń se àlejò ni ilẹ̀ àjòjì.”

4. Èkejì ń jẹ́ Élíásérì (alátìlẹ́yìn); ó wí pé, “Ọlọ́run baba mi ni alátìlẹ́yìn mi, ó sì gbà mí là kúrò lọ́wọ́ idà Fáráò.”

5. Jẹ́tírò, àna Mósè, òun àti aya àti àwọn ọmọ Mósè tọ̀ ọ́ wá nínú ihà tí ó tẹ̀dó sí, nítòsí òkè Ọlọ́run.

Ka pipe ipin Ékísódù 18