Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 17:3-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ṣùgbọ́n òùngbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Éjíbítì láti mú kí òùngbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òùngbẹ.”

4. Nígbà náà ni Mósè gbé ohùn rẹ̀ sókè sí Olúwa pé; “Kí ni kí èmi kí ó ṣe fún àwọn ènìyàn yìí? Wọ́n múra tan láti sọ mi ni òkúta.”

5. Olúwa sì dá Mósè lóhùn pé, “Má a lọ ṣíwájú àwọn ènìyàn, mú nínú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú rẹ, mú ọ̀pá tí ìwọ fi lu odò Náìlì lọ́wọ́ kí ó sì máa lọ.

6. Èmi yóò dúró ni ibẹ̀ dè ọ ni orí àpáta ni Hórébù. Ìwọ ó sì lu àpáta, omi yóò sì jáde nínú rẹ̀ fún àwọn ènìyàn láti mu.” Mósè sì se bẹ́ẹ̀ ni iwájú àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì.

7. Ó sì sọ orúkọ ibẹ̀ ni Másá (ìdánwò) àti Méríba (kíkùn) nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀, wọ́n sì dán Olúwa wò, wọ́n wí pé, “Ǹjẹ́ Olúwa ń bẹ láàrin wa tàbí kò sí?”

8. Àwọn ara Ámélékì jáde, wọ́n sì dìde ogun sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Réfídímù.

9. Mósè sì sọ fún Jọ́súà pé, “Yàn lára àwọn ọkùnrin fún wa, kí wọn ó sì jáde lọ bá àwọn ará Ámélékì jà. Ní ọ̀la, èmi yóò dúró ni orí òkè pẹ̀lú ọ̀pá Ọlọ́run ní ọwọ́ mi.”

10. Jósúà se bí Mósè ti wí fún un, ó sì bá àwọn ará Ámélékì jagun; nígbà tí Mósè, Árónì àti Húrì lọ sí orí òkè náà.

11. Níwọ̀n ìgbà tí Mósè bá gbé apá rẹ̀ sókè, Ísírẹ́lì n borí ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá sì rẹ apá rẹ̀ sílẹ̀, Ámélékì a sì borí.

12. Ṣùgbọ́n apá ń ro Mósè; Wọ́n mú òkúta, wọ́n sì fi sí abẹ́ rẹ̀, ó sì jókòó lé òkúta náà: Árónì àti Húrì sì mu ní apá rẹ̀, ọ̀kan ní apá ọ̀tún àti èkejì ni apá òsì; apá rẹ̀ méjèèjì sì dúró gangan títí di ìgbà ti òòrùn wọ.

13. Jósúà sì fi ojú idà sẹ́gun àwọn ará Ámélékì.

14. Olúwa sì sọ fun Mósè pé. “Kọ èyí sì inú ìwé fún ìrántí, kí o sì sọ fún Jóṣúà pẹ̀lú; nítorí èmi yóò pa ìràntí Ámélékì run pátapáta kúrò lábẹ́ ọ̀run.”

15. Mósè sì tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì sọ orúkọ pẹpẹ náà ní Olúwa ni àṣíá mi (Jóhéfà-Nisì).

16. Ó wí pé, “A gbé ọwọ́ sókè sí ìtẹ́ Olúwa. Olúwa yóò bá Ámélékì jagun láti ìran dé ìran.”

Ka pipe ipin Ékísódù 17