Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 14:7-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Éjíbítì, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn.

8. Olúwa ṣe ọkàn Fáráò ọba Éjíbítì le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.

9. Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì.

10. Bí Fáráò ti súnmọ́ tòsí ọ̀dọ̀ wọn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé ojú wọn sókè, wọn sì rí àwọn ará Éjíbítì tó súnmọ́ wọn. Ẹ̀rù ńlá sì bá àwọn ará Ísírẹ́lì, wọ́n kígbe sókè sí Olúwa.

11. Wọ́n sọ fún Móse pé, “Ṣe nítorí pé kò sí ibojì ni Éjíbítì ní ìwọ se mú wa wá láti kú sínú ihà? Kí ni èyí tí ìwọ ṣe sí wa ti ìwọ fi mú wa jáde láti Éjíbítì wá?

12. Ǹjẹ́ èyí kọ́ ni àwa sọ fún ọ ni Éjíbítì, ‘Fi wá sílẹ̀, jẹ́ kí àwa máa sin ará Éjíbítì’? Nítorí kò bá sàn fún wa kí a sin àwọn ará Éjíbítì ju kí a kú sínú ihà yìí lọ!”

13. Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ ma bẹ̀rù, ẹ dúró sinsin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fifún un yín lónìí; Àwọn ará Éjíbítì ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.

14. Olúwa yóò jà fún un yin; kí ẹ̀yin kí ó sáà mu sùúrù.”

15. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì kí wọn máa tẹ̀ṣíwájú.

Ka pipe ipin Ékísódù 14