Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 14:13-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà ni Mósè sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ ma bẹ̀rù, ẹ dúró sinsin kí ẹ sì rí ìdáǹdè tí Olúwa yóò fifún un yín lónìí; Àwọn ará Éjíbítì ti ẹ̀yin rí lónìí ni ẹ kò ni tún padà rí wọn mọ́.

14. Olúwa yóò jà fún un yin; kí ẹ̀yin kí ó sáà mu sùúrù.”

15. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń ké pè mí? Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì kí wọn máa tẹ̀ṣíwájú.

16. Ṣùgbọ́n, gbé ọ̀pá rẹ̀ sókè, kí o sì na ọwọ́ rẹ sí orí omi òkun, kí ó lè pín níyà kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè la òkun kọjá ni orí ìyàngbẹ ilẹ̀.

17. Nígbà náà ni èmi yóò ṣé ọkàn àwọn ará Éjíbítì le, wọn yóò sì máa lépa wọn; Èmi yóò gba ògo fún ara mi lórí Fáráò; lórí gbogbo ogun rẹ̀, lórí kẹ̀kẹ́-ògun àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.

18. Àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa nígbà ti èmi bá gba ògo fún ara mi lórí Fáráò: lórí kẹ̀kẹ́-ogun rẹ̀ àti lórí àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀.”

19. Nígbà náà ni ańgẹ́lì Ọlọ́run tó ti ń ṣááju ogun Ísírẹ́lì lọ, padà o sì rìn ni ẹ̀yìn wọn; Òpó ìkùùkuu tí ń rìn ni iwájú wọn sì padà sí í rìn ni ẹ̀yìn wọn.

20. Ó sì wà láàrin àwọn ọmọ ogun Éjíbítì àti Ísírẹ́lì. Ìkùùkuu sì su òkùnkùn sí àwọn ará Éjíbítì ni òru náà. Ṣùgbọ́n ó tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn Ísírẹ́lì ni òru náà; Ọ̀kan kò sì súnmọ́ èkejì ni gbogbo òru náà.

21. Nígbà náà ni Mósè na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, ni gbogbo òru náà ni Olúwa fi lé òkun sẹ́yìn pẹ̀lú ìjì líle láti ìlà-oòrùn wá, ó sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀. Omi òkun sì pínyà,

22. àwọn ọmọ Ísírẹ́lì si la ìyàngbẹ ilẹ̀ kọjá nínú òkun pẹ̀lú ògiri omi ní ọ̀tún àti òsì.

23. Àwọn ará Éjíbítì sì ń lépa wọn, gbogbo ẹsin Fáráò, kẹ́kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.

24. Ní ìsọ́ òwúrọ̀ (láàárin ago mẹ́ta sí mẹ́ta òwúrọ̀) Olúwa bojúwo ogun àwọn ará Éjíbítì láàrin òpó iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ ogun Éjíbítì.

Ka pipe ipin Ékísódù 14