Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 14:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sọ fún Mósè pé

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí wọn padà sẹ́yìn, kí wọ́n sì pàgọ́ sí tòsí Pi-Háhírótù láàrin Mígídólù òun òkun, kí wọn kí ó pàgọ́ sí ẹ̀bá òkun, ní òdìkejì Baali-Séfóní.

3. Fáráò yóò ronu pé àwọn ọmọ Isírẹ́lì ń ráre káàkiri ní ìdààmú ni àti wí pé ihà náà ti sé wọn mọ́.

4. Èmi yóò sé ọkàn Fáráò le ti yóò fi lépa wọn. Ṣùgbọ́n èmi yóò gba ògo fún ará mi láti ìpaṣẹ̀ Fáráò àti ogun rẹ̀, àti pé àwọn ará Éjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.” Àwọn Isírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀.

5. Nígbà tí wọ́n sọ fún ọba Éjíbítì pé àwọn ènìyàn náà ti sá lọ, ọkàn Fáráò àti àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ yí padà sí àwọn ènìyàn, wọ́n sì wí pé, “Kí ni ohun tí àwa ṣe yìí? Àwa ti jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó lọ, a sì ti pàdánù ìsìnrú wọn.”

6. Ó sì di kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀,

7. ó mú ẹgbẹ̀ta (600) ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ tí ó jáfáfá jùlọ àti gbogbo ọmọ ogun oníkẹ̀kẹ́ mìíràn ní Éjíbítì, olórí sì wà fún olúkúlùkù wọn.

8. Olúwa ṣe ọkàn Fáráò ọba Éjíbítì le, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lépa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jáde lọ ní àìbẹ̀rù.

9. Àwọn ará Éjíbítì ń lépa wọn pẹ̀lú gbogbo ẹsin kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀, wọ́n sì lé wọn bá ni ibi tí wọ́n pa àgọ́ sí lẹ́bá òkun ní ìhà Pi-Hahírótù, ni òdì kejì Baali-Ṣéfónì.

Ka pipe ipin Ékísódù 14