Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 6:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí Olúwa Ọlọ́run yín pàṣẹ fún mi láti kọ́ ọ yín kí ẹ lè kíyèsí i, ní ilẹ̀ náà tí ẹ ó ni lẹ́yìn tí ẹ bá kọjá a Jọ́dánì.

2. Kí ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn, lẹ́yìn wọn bá à lè bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run yín, ní gbogbo ìgbà tí ẹ bá wà láyé, nípa pípa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ tí mo fún un yín mọ́, kí ẹ bá à lè pẹ́ lórí ilẹ̀.

3. Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, kí o sì ṣọ́ra láti gbọ́ran, kí ó bá à lè dára fún ọ, kí o bá à lè gbilẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ ti ṣèlérí fún ọ.

4. Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, Olúwa Ọlọ́run wa, Olúwa kan ṣoṣo ni.

5. Fẹ́ràn Olúwa Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo àyà rẹ àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo agbára rẹ.

6. Àwọn àṣẹ tí mo fún un yín lónìí gbọdọ̀ má a wà lóókan àyà yín.

7. Ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín gidigidi. Bí ẹ bá jókòó nínú ilé, ẹ jíròrò nípa wọn, àti nígbà tí ẹ bá ń rìn ní ojú ọ̀nà, bí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.

8. Ẹ ṣo wọ́n sí ọwọ́ yín fún àmì, ẹ so ó mọ́ iwájú orí yín.

9. Ẹ kọ wọ́n sára àwọn férémù ìlẹ̀kùn àwọn ilé yín àti sí ara ìlẹ̀kùn ọ̀nà òde yín.

10. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú ọ dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín: Fún Ábúráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù láti fi fún un yín, Ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ,

11. àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kàǹga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso ólífì tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n: Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó,

Ka pipe ipin Deutarónómì 6