Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:46-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

46. Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì; ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀.

47. Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ógù ọba Básánì àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.

48. Ilẹ̀ wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ láti Áréórì ní etí odò Ánónì dé orí òkè Ṣíhónì (èyí ni Hámónì).

49. Àti gbogbo aginjù ní ìlà oòrùn Jọ́dánì títí dé òkun aginjù (òkun iyọ̀) ní ìṣàlẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4