Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:41-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Mósè sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì.

42. Níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn le sálọ, bí ó bá ṣe pé ó ṣèèṣì pa aládúgbò rẹ̀ láìsí ìkùnsínú láàrin wọn. Òun le sálọ sí èyíkéyìí nínú ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, fún ìgbàlà ẹ̀mí ara rẹ̀.

43. Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Bésérì ní òkè olórí títẹ́ tí ó wà ní aṣálẹ̀, fún àwọn ará Rúbẹ́nì; Rámótì ní Gílíádì fún àwọn ará Gádì àti Gólánì ní Básánì fún àwọn ará Mánásè.

44. Èyí ni òfin tí Mósè gbékalẹ̀ fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

45. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ ìlànà àti òfin tí Mósè fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Éjíbítì.

46. Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì; ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀.

47. Wọ́n gba ilẹ̀ rẹ̀, àti ilẹ̀ Ógù ọba Básánì àwọn ọba Ámórì méjèèjì tí ń bẹ ní ìlà oòrùn Jọ́dánì.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4