Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:31-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín aláàánú ni, kò ní gbàgbé tàbí pa yín rẹ́ tàbí kó gbàgbé májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín, èyí tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ìbúra.

32. Ẹ bèèrè báyìí nípa ti àwọn ọjọ́ ìgbàanì ṣáájú kí a tó bí i yín, láti ìgbà tí Ọlọ́run ti dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé. Ẹ bèèrè láti igun ọ̀run kan sí èkejì. Ǹjẹ́ irú nǹkan olókìkì báyìí: ti ṣẹlẹ̀ rí? Ǹjẹ́ a ti gbọ́ irú u rẹ̀ rí?

33. Ǹjẹ́ àwọn ènìyàn mìíràn tí ì gbọ́ ohùn Ọlọ́run rí, tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti inú iná, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin ti gbọ́ tí ẹ sì yè?

34. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kan ti gbìyànjú àti mú orílẹ̀ èdè kan jáde kúrò nínú òmíràn fúnra rẹ̀ rí, nípa ìdánwò, nípa iṣẹ́ àmì, àti iṣẹ́ ìyanu nípa ogun, tàbí nípa ọwọ́ agbára tàbí nína ọwọ́, tàbí nípa iṣẹ́ ipá àti agbára ńlá: gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa Ọlọ́run yín ṣe fún un yín ní Éjíbítì ní ojú ẹ̀yin tìká ara yín?

35. A fi gbogbo nǹkan wọ̀nyí hàn yín kí ẹ bá a lè gbà pé Olúwa ni Ọlọ́run. Kò sì sí ẹlòmíràn lẹ́yìn rẹ̀.

36. Ó jẹ́ kí ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀ láti ọ̀run wá, láti kọ́ ọ yín. Ní aye, ó fi iná ńlá rẹ̀ hàn yín, ẹ sì gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àárin iná wá,

37. torí pé ó fẹ́ràn àwọn baba ńlá yín, ó sì yan àwọn ọmọ wọn ní ipò lẹ́yìn wọn. Nípa ìwà láàyè àti nípa agbára ńlá rẹ̀ ni ó fi mú un yín kúrò ní Éjíbítì.

38. Láti lé àwọn orílẹ̀ èdè tí ó tóbi tí ó sì lágbára níwájú yín; láti le è mú un yín wá sí ilẹ̀ wọn kí ẹ lè jogún rẹ̀ bí ó ti rí lónìí.

39. Ẹ gbà kí ẹ sì fi sọ́kàn lónìí pé Olúwa ni Ọlọ́run lókè ọ̀run lọ́hùn ún àti ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn ín. Kò sí òmíràn mọ́.

40. Ẹ pa àwọn ìlànà àti àṣẹ rẹ̀ mọ́ tí mo ń fún un yín lónìí; kí ó ba à le è yẹ yín, kí ẹ̀yin sì le è pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín ní gbogbo ìgbà.

41. Mósè sì ya àwọn ìlú mẹ́ta kan sọ́tọ̀ ní apá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì.

42. Níbi tí ẹnikẹ́ni tí ó bá pa ènìyàn le sálọ, bí ó bá ṣe pé ó ṣèèṣì pa aládúgbò rẹ̀ láìsí ìkùnsínú láàrin wọn. Òun le sálọ sí èyíkéyìí nínú ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, fún ìgbàlà ẹ̀mí ara rẹ̀.

43. Àwọn ìlú mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà nìwọ̀nyí: Bésérì ní òkè olórí títẹ́ tí ó wà ní aṣálẹ̀, fún àwọn ará Rúbẹ́nì; Rámótì ní Gílíádì fún àwọn ará Gádì àti Gólánì ní Básánì fún àwọn ará Mánásè.

44. Èyí ni òfin tí Mósè gbékalẹ̀ fún àwọn ará Ísírẹ́lì.

45. Wọ̀nyí ni àwọn àṣẹ ìlànà àti òfin tí Mósè fún wọn lẹ́yìn tí wọ́n ti jáde kúrò ní Éjíbítì.

46. Tí wọ́n sì wà ní ẹ̀bá àfonífojì Bétí Péórì ní ìlà oòrùn Jọ́dánì; ní ilẹ̀ Ṣíhónì, ọba àwọn Ámórì tí ó jọba Hésíbónì tí Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, bí wọ́n ṣe ń ti Éjíbítì bọ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4