Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 4:11-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ẹ̀yin súnmọ́ tòsí ẹ sì dúró ní ẹṣẹ̀ òkè náà, nígbà tí òkè náà yọná lala lọ sókè ọrun pẹ̀lú ìkúùkù ńlá, àti òkùnkùn biribiri.

12. Olúwa sì bá yín sọ̀rọ̀ láti àárin iná náà wá. Ẹ gbọ́ àwọn ìró ohùn, ṣùgbọ́n ẹ kò rí ẹnikẹ́ni, ohùn nìkan ni ẹ gbọ́.

13. Ó sọ àwọn májẹ̀mú rẹ̀ fún un yín àní àwọn òfin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí ó pàṣẹ fún un yín láti máa tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sórí sílétì òkúta méjì.

14. Olúwa sọ fún mi nígbà tí ẹ gbọdọ̀ tẹ̀lée, nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ ìní yín lẹ́yìn tí ẹ bá la Jọ́dánì kọjá.

15. Ẹ kíyèsára gidigidi, torí pé, ẹ kò rí ìrísí ohunkóhun ní ọjọ́ tí Olúwa bá yín sọ̀rọ̀ ní Hórébù láti àárin iná wá. Torí náà ẹ sọ́ra yín gidigidi,

16. kí ẹ ma ba à ba ara yín jẹ́ nípa ṣíṣe ère fún ara yín, àní ère lóríṣìíríṣìí yálà èyí tí ó ní ìrísí ọkùnrin tàbí tí obìnrin,

17. tàbí ti ẹranko orí ilẹ̀, tàbí ti ẹyẹ tí ń fò lófuurufú,

18. tàbí ti àwòrán onírúurú ẹ̀dá tí ń fà lórí ilẹ̀, tàbí ti ẹja nínú omi.

19. Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí òòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ débi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀ èdè lábẹ́ ọ̀run.

20. Olúwa Ọlọ́run yín sì ti mú ẹ̀yin jáde kúrò nínú iná ìléru ńlá, àní ní Ị́jíbítì, láti lè jẹ́ ènìyàn ìní i rẹ̀, bí ẹ̀yin ti jẹ́ báyìí.

21. Inú Olúwa ru sí mi nítorí yín, ó sì ti búra pé èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, èmi kì yóò sì wọ ilẹ̀ rere tí Olúwa Ọlọ́run fi fún un yín, ní ìní yín.

22. Èmi yóò kú ní ilẹ̀ yìí, èmi kì yóò la Jọ́dánì kọjá, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti fẹ́ rékọjá sí òdì kejì odò láti gba ilẹ̀ rere náà.

23. Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe gbàgbé májẹ̀mú Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti bá a yín dá: Ẹ má ṣe ṣe ère ní ìrísí ohunkóhun fún ara yín, èèwọ̀ ni Olúwa Ọlọ́run yín kà á sí.

24. Torí pé iná ajónirun ni Olúwa Ọlọ́run yín, Ọlọ́run owú ni.

Ka pipe ipin Deutarónómì 4