Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:37-51 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Yóò wí pé: “Òrìṣà a wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,

38. ọlọ́run tí ó jẹ ara ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

39. “Wòó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

40. Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:Èmi ti wà láàyè títí láé,

41. nígbà tí mo bá pọ́n idà dídán miàti tí mo bá sì fi ọwọ́ mi lé ìdájọ́,Èmi yóò san ẹ̀san fún àwọn ọ̀tá miÈmi kò sì san fún àwọn tí ó kórìíra à mi.

42. Èmi yóò mú ọfà mu ẹ̀jẹ̀,nígbà tí idà mi bá jẹ ẹran:Ẹ̀jẹ̀ ẹni pípa àti ẹni ìgbèkùn,orí àwọn asáájú ọlá.”

43. Ẹyọ̀ ẹ̀yin orílẹ̀ èdè, pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀nítorí òun yóò gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀;yóò sì gbẹ̀san lára àwọn ọ̀ta a rẹ̀yóò sì se ètùtù fún ilẹ̀ rẹ̀ àti ènìyàn.

44. Móṣè wà pẹ̀lú u Jóṣúà ọmọ Núnì ó sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ orin yìí sí etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn.

45. Nígbà tí Móṣè parí i kíka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí Ísírẹ́lì.

46. Ó sọ fún un pé, “Ẹ gbé ọkàn an yín lé gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti ṣọ láàrin yín lónìí, kí ẹ̀yin lè pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti gbọ́ran àti láti ṣe gbogbo ọ̀rọ̀ inú òfin yìí.

47. Wọn kì í se ọ̀rọ̀ asán fún ọ, ìyè e yín ni wọ́n. Nípa wọn ni ẹ̀yin yóò gbé pẹ́ lórí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ń gòkè e Jọ́dánì lọ láti gbà.”

48. Ní ọjọ́ kan náà, Olúwa sọ fún Móṣè pé,

49. “Gòkè lọ sí Ábárímù sí òkè Nébò ní Móábù, tí ó kọjú sí Jẹ́ríkò, kí o sì wo ilẹ̀ Kénánì ilẹ̀ tí mo ń fi fún àwọn ọmọ Isírẹ́lì, bí ìní i wọn.

50. Ní orí òkè tí ìwọ ń gùn lọ ìwọ yóò kú níbẹ̀, kí a sì sin ọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin in rẹ Árónì ti kú ní orí òkè Hórù tí a sì sin ín pẹ̀lú àwọn ènìyàn an rẹ̀.

51. Ìdí ni pé ẹ̀yin méjèèjì ṣẹ̀ sí mi láàrin àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ibi omi Móríbà Kádésì ní ihà Ṣínì àti nítorí ẹ̀yin kò yà mí sí mímọ́ láàrin àwọn ọmọ Isírẹ́lì.

Ka pipe ipin Deutarónómì 32