Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:31-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí Àpáta wa,àní àwọn ọ̀ta wa tìkálára wọn ń ṣe onídàájọ́.

32. Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sódómùàti ti ìgbẹ́ ẹ Gòmórà.Èṣo àjàrà wọn kún fún oró,Ìdì wọn korò.

33. Ọtí wáìnì ni ìwọ ti dírágónì,àti oró mímú ti pamọ́lẹ̀.

34. “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dìí ní ìṣúra à mi?

35. Ti èmi ni láti gbẹ̀san; Èmi yóò san án fún wọnní àkókò tí ẹ̀sẹ̀ wọn yóò yọ;ọjọ́ ìdàmú wọn sún mọ́ etíléohun tí ó sì ń bọ̀ wá bá wọn yára bọ̀.”

36. Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn an rẹ̀yóò sì ṣàánú fún àwọn ìránṣẹ́ ẹ rẹ̀nígbà tí ó bá rí i pé agbára wọn lọ tántí kò sì sí ẹnìkan tí ó kù, ẹrú tàbí ọmọ.

37. Yóò wí pé: “Òrìṣà a wọn dà báyìí,àpáta tí wọ́n fi ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé e wọn,

38. ọlọ́run tí ó jẹ ara ẹbọ wọntí ó ti mu ọtí i wáìnì ẹbọ ohun mímu wọn?Jẹ́ kí wọn dìde láti gbà wọ́n!Jẹ́ kí wọn ṣe ààbò fún un yín!

39. “Wòó báyìí pé: èmi fúnra à mi, èmi ni!Kò sí ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn mi.Mo sọ di kíkú mo sì tún sọ di ààyè,mo ti ṣá lọ́gbẹ́ Èmi yóò sì mu jiná,kò sí ẹni tí ó lè gbà kúrò lọ́wọ́ ọ̀ mi.

40. Mo gbé ọwọ́ mi sókè ọ̀run mo sì wí pé:Èmi ti wà láàyè títí láé,

Ka pipe ipin Deutarónómì 32