Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:23-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

24. Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

25. Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.

26. Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn,

27. nítorí bí mo ti bẹ̀rù ìbínú ọ̀ta,kí àwọn ọ̀ta a wọn kí ó mába à wí pé, ‘Ọwọ́ ọ wa lékè ni;kì í sì í ṣe Olúwa ni ó ṣe gbogbo èyí.’ ”

28. Wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè tí kò ní ìmọ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò sí òye nínú un wọn.

29. Bí ó ṣe pé wọ́n gbọ́n, kí òye yìí sì yé wọnkí wọn ròbí ìgbẹ̀yìn in wọn yóò ti rí!

30. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè lé ẹgbẹ̀rún,tàbí tí ẹni méjì sì lè lé ẹgbàaàrún sá,bí kò ṣe pé Àpáta wọn ti tà wọ́n,bí kò ṣe pé Olúwa wọn ti fi wọ́n tọrẹ?

31. Nítorí pé àpáta wọn kò dàbí Àpáta wa,àní àwọn ọ̀ta wa tìkálára wọn ń ṣe onídàájọ́.

32. Igi àjàrà a wọn wá láti igi àjàrà Sódómùàti ti ìgbẹ́ ẹ Gòmórà.Èṣo àjàrà wọn kún fún oró,Ìdì wọn korò.

33. Ọtí wáìnì ni ìwọ ti dírágónì,àti oró mímú ti pamọ́lẹ̀.

34. “Èmi kò to èyí jọ ní ìpamọ́èmi kò sì fi èdìdì dìí ní ìṣúra à mi?

Ka pipe ipin Deutarónómì 32