Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:23-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. “Èmi yóò kó àwọn ohun búburú lé wọn lóríèmi ó sì na ọfà mi tán sí wọn lára.

24. Èmi yóò mú wọn gbẹ,ooru gbígbóná àti ìparun kíkorò ni a ó fi run wọ́n.Pẹ̀lú oró ohun tí ń rákò nínú erùpẹ̀.

25. Idà ní òde,àti ìpayà nínú ìyẹ̀wù.Ni yóò run ọmọkùnrin àti wúndíá,ọmọ ẹnu-ọmú àti arúgbó eléwù irun pẹ̀lú.

26. Mo ní èmi yóò tú wọn káèmi yóò sì mú ìrántí i wọn dà kúró nínú àwọn ènìyàn,

Ka pipe ipin Deutarónómì 32