Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 31:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Móṣè jáde tí ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí gbogbo Ísírẹ́lì pé:

2. “Mo jẹ́ ọmọ ọgọ́fà ọdún báyìí àti pé èmi kò ni lè darí i yín mọ́. Olúwa ti sọ fún mi pé, ‘O kò ní kọjá Jọ́dánì.’

3. Olúwa Ọlọ́run rẹ fúnra rẹ̀ ni yóò rékọjá fún ọ. Yóò pa àwọn orílẹ̀ èdè yìí run níwájú ù rẹ, ìwọ yóò sì mú ìní ilẹ̀ wọn, Jósúà náà yóò rékọjá fún ọ, bí Olúwa ti sọ.

4. Olúwa yóò sì ṣe fún wọn ohun tí ó ti ṣe sí Ṣíhónì àti sí Ógù ọba Ámórì, tí ó parun pẹ̀lú ilẹ̀ ẹ wọn.

5. Olúwa yóò fi wọ́n fún ọ, kí o sì ṣe sí wọn gbogbo èyí tí mo ti pa láṣẹ fún ọ.

6. Jẹ́ alágbára kí o sì ní ìgboyà. Má se bẹ̀rù tàbí jáyà nítorí i wọn, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń lọ pẹ̀lú ù rẹ; Òun kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀.”

7. Nígbà náà ni Mósè pe Jóṣúà ó sì wí fún un níwájú gbogbo Ísírẹ́lì pé, “Jẹ́ alágbára àti onígboyà, nítorí o ní láti lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fún wọn, kí o sì pín ilẹ̀ náà láàrin wọn bí ogún wọn.

8. Olúwa fúnra rẹ̀ ń lọ níwájú rẹ yóò sì wà pẹ̀lú ù rẹ; kò ní fi ọ́ sìlẹ̀ tàbí kọ̀ ọ́ sìlẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù má sì ṣe fòyà.”

9. Nígbà náà ni Móṣè kọ òfin yìí kalẹ̀ ó sì fi fún àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, tí ń gbé àpótí i májẹ̀mú Olúwa, àti fún gbogbo àwọn àgbà ní Ísírẹ́lì.

10. Nígbà náà ni Móṣè pàṣẹ fún wọn, “Ní òpin ọdún méje méje, ní àkókò ọdún ìdásílẹ̀, nígbà àjọ àwọn àgọ́.

11. Nígbà tí gbogbo Ísírẹ́lì bá wá láti fi ara hàn níwájú Olúwa Ọlọ́run wa ní ibi tí yóò yàn, ìwọ yóò ka òfin yìí níwájú wọn sí etí ìgbọ́ wọn.

12. Pe àwọn ènìyàn jọ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin àti àwọn àlejò tí ń gbé àwọn ìlú u yín kí wọn lè fetí sí i kí wọn sì lè kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ kí wọn sì rọra tẹ̀lé gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí.

13. Àwọn ọmọ wọn tí wọn kò mọ òfin yìí, gbọdọ̀ gbọ́ kí wọn sì kọ́ láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ níwọ̀n ìgbà tí o tí ń gbé ní ilẹ̀ tí ò ń kọjá la Jọ́dánì lọ láti ni.”

14. Olúwa sọ fún Móṣè pé, “Ọjọ́ ikú rẹ ti súnmọ́tílé báyìí. Pe Jóṣúà kí ẹ sì fi ara yín hàn nínú àgọ́ àjọ, níbi tí èmi yóò ti fi àṣẹ fún un.” Nígbà náà ni Móṣè àti Jóṣúà wá, wọ́n sì fara wọn hàn níbi àgọ́ àjọ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 31