Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 3:20-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. títí di ìgbà tí Olúwa yóò fún àwọn arákùnrin yín ní ìsinmi bí ó ti fún un yín, àti ìgbà tí àwọn náà yóò fi gba ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run yín ti fún wọn ní ìhà kejì Jọ́dánì. Nígbà náà ni ọ̀kọ̀ọ̀kan yín tó lè padà lọ sí ìní rẹ̀ tí mo fún un.”

21. Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún Jósúà pé, “Ìwọ tí fi ojú rẹ rí ohun gbogbo tí Olúwa Ọlọ́run rẹ tí ṣe sí àwọn ọba méjèèjì wọ̀nyí. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò ṣe sí àwọn ilẹ̀ ọba tí ẹ̀yin n lọ.

22. Ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, Olúwa Ọlọ́run yín tìkálára rẹ̀ ni yóò jà fún un yín.”

23. Nígbà náà ni mo bẹ Olúwa wí pé,

24. “Ọlọ́run Alágbára, ìwọ tí ń fi títóbi rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ han ìránṣẹ́ rẹ. Ọlọ́run wo ló tó bẹ́ẹ̀ láyé àti lọ́run tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ agbára ńlá tí o ti ṣe?

25. Jẹ́ kí n kọjá lọ wo ilẹ̀ rere ti ìkọjá Jọ́dánì: Ilẹ̀ òkè dídára nì àti Lẹ́bánónì.”

26. Ṣùgbọ́n torí i ti yín, Olúwa Ọlọ́run bínú sí mi kò sì gbọ́ tèmi. Olúwa sọ wí pé, “Ó tó gẹ́ẹ́, ìwọ kò gbọdọ̀ sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ yìí sí mi mọ́.

27. Gòkè lọ sí orí òkè Písígà, sì wò yíká ìwọ̀ oòrùn, ìlà oòrun, àríwá àti gúúsù. Fi ojú ara rẹ wo ilẹ̀ náà níwọ̀n bí ìwọ kò tí ní kọjá Jọ́dánì yìí.

28. Ṣùgbọ́n yan Jósúà, kí o sì gbà á níyànjú, mú un lọ́kàn le, torí pé òun ni yóò ṣíwájú àwọn ènìyàn wọ̀nyí kọjá, yóò sì jẹ́ kí wọn jogún ilẹ̀ náà tí ìwọ yóò rí.”

29. Báyi ni a dúró ní àfonífojì ní ẹ̀bá Bétí-Péórì.

Ka pipe ipin Deutarónómì 3