Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:52-60 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

52. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ títí tí odi ìdáàbòbò gíga yẹn tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé yóò fi wó lulẹ̀. Wọn yóò gbógun ti gbogbo ìlú ù rẹ jákèjádò ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ.

53. Nítorí ìyà tí ọ̀ta à rẹ yóò fi jẹ ọ́ nígbà ìgbógun tì, ìwọ yóò jẹ, ẹran ara ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí Olúwa Ọlọ́run ti fi fún ọ.

54. Ènìyàn jẹ́jẹ́ àti onímọ̀ jùlọ kò ní ní àánú fún arákùnrin ara rẹ̀ tàbí ìyàwó tí ó fẹ́ràn tàbí àwọn ọmọ rẹ̀ tí o wà láàyè,

55. Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fún ẹnikẹ́ni nínú ẹran-ara àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó ń jẹ, nítorí kò sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún un nínú ìdótì náà àti ìpọ́njú tí àwọn ọ̀ta yóò fi pọ́n ọ lójú ní ìlú u rẹ.

56. Obìnrin tí àwọ̀ rẹ̀ tutù nínú u yín, tí ó si ṣe ẹlẹgẹ́, tí kò jẹ́ dáṣà láti fi àtẹ́lẹṣẹ̀ ẹ rẹ̀ kan ilẹ̀ nítorí ìkẹ́ra àti ìwà ẹlẹgẹ́, ojú u rẹ̀ yóò korò sí ọkọ oókan àyà a rẹ̀, àti sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ rẹ̀ obìnrin

57. ọmọ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láti inú u rẹ̀ àti àwọn ọmọ tí ó ti bí. Nítorí ó fẹ́ láti jẹ wọ́n ní ìkọ̀kọ̀ nígbà ìgbógun tì àti ní ìgbà ìpọ́njú tí ọ̀ta rẹ yóò fi jẹ ọ́ nínú àwọn ìlú rẹ.

58. Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ,

59. Olúwa yóò rán ìyọnu tí ó ní ìbẹ̀rù sórí rẹ, àti sórí irú ọmọ ọ̀ rẹ, àti àwọn àjálù pípẹ́, àti ìmúna àti àìsàn ìlọ́ra.

60. Olúwa yóò mú gbogbo àrùn Éjíbítì tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá sórí ì rẹ, wọn yóò sì so mọ́ ọ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28