Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 26:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá níyà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.

7. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.

8. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Éjíbítì pẹ̀lu ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.

9. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin;

Ka pipe ipin Deutarónómì 26