Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 26:5-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Árámíà, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Éjíbítì pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀ èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn.

6. Ṣùgbọ́n àwọn ará Éjíbítì ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá níyà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe.

7. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa.

8. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Éjíbítì pẹ̀lu ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu.

9. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin;

10. àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Gbé agbọ̀n náà ṣíwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀.

11. Ìwọ àti àwọn ọmọ Léfì àti àjòjì láàrin yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

12. Nígbà tí o bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹ́ta sọ́tọ̀ sí apákan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Léfì, àjòjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó.

13. Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Léfì, àwọn àjòjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pa láṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn.

14. Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pa láṣẹ fún mi.

15. Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àwọn babańlá wa, ilẹ̀ tí ó ń ṣàn fún wàrà àti fún oyin.”

16. Olúwa Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ.

17. Ìwọ jẹ́wọ́ Olúwa ní òní pé Olúwa ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i.

18. Ní òní ni Olúwa jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́.

19. Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.

Ka pipe ipin Deutarónómì 26